Warning: Cannot modify header information - headers already sent by (output started at /var/www/includes/database.mysqli.inc:134) in /var/www/includes/bootstrap.inc on line 729

Warning: Cannot modify header information - headers already sent by (output started at /var/www/includes/database.mysqli.inc:134) in /var/www/includes/bootstrap.inc on line 730

Warning: Cannot modify header information - headers already sent by (output started at /var/www/includes/database.mysqli.inc:134) in /var/www/includes/bootstrap.inc on line 731

Warning: Cannot modify header information - headers already sent by (output started at /var/www/includes/database.mysqli.inc:134) in /var/www/includes/bootstrap.inc on line 732
13.0 Otura Meji | Africa's Sources of Knowledge - Digital Library
warning: Cannot modify header information - headers already sent by (output started at /var/www/includes/database.mysqli.inc:134) in /var/www/includes/common.inc on line 153.

13.0 Otura Meji

13.0 Otura Meji

|
||
|
|

|
||
|
|

Otura Meji 1:
Odu Ifa ti a dalẹ yii, Otua Meji lo wa nlẹ yii. Ẹni ta da a fun, Ifa sọ fun eleyii wipe ko mojuto ẹsin. To ba jẹ pe musulumi ni, ko lọ kewu. Ko mojuto ẹsin daadaa, kọ lọ kewu o, to ba jẹ pe iran musulumi ni. To ba jẹ pe eleyii, yio ṣe babalawo, to si tun jẹ pe iran musulumi ni baba rẹ tẹlẹ, ko ṣe mejeji pọ, o bara wọn mu. Ifa laṣeyọri wa fun eleyii. Kewu gidi ni kọ lọ ke, kewu lọna rẹ. Loju Otua Meji. Ifa ni to ba ti lọ kewu, gbogbo nkan o wa rọ ọ lọrun. Aṣeyọri yio de ba. Ifa sọọ bẹẹ loju Otua Meji. Nibi Ifa gba to fi sọ bẹẹ. O ni:

Dagadamba n fura ọsẹyẹ oko gbọ mọle Aworokonjobi a dia fun Ọrunmila. Baba n lọ re gba gambi, a gba gambi o, a gba a wa, a le we lawani a gbe ede bọrun. Ifa wa wa di mọle.

Ifa ni keleyii lọ kewu, Ifa… to ba ti kewu, o laṣeyọri wa fun. Gbogbo ohun pe, oke ṣoro rẹ, o ni yio lọle ni. Bẹẹ ni Ifa sọ, lodu Otua Meji. Bẹẹ ni.

Otura Meji 2:
Otura Meji… Ifa yii tun sọ feleyii wipe keleyii kọ ṣọra rẹ daadaa. Ko mọ pe agba nbẹ. Ẹni to ba ba nibi kan, to ba jọga fun, ko gba lọga. Kaṣeyọri o le ba de ba. Tori ohun toun na ba ṣe ni o gba o. Ifa ni teleyii ba ṣe ni o gba, ko ma huwa buruku fun ẹni to jẹ aṣaju rẹ. Ko ma rifin, Ifa ni to ba ṣe fun agba n loun na o gba. Ifa ni to ba ti le tẹriba fagba, to si gba pe ẹni to wa iwaju yii, ọga lo jẹ fun oun, Ifa ni yio ṣaseyọri. Loju Otua Meji naa lo sọ bẹẹ. Nibi Ifa gba to fi sọ bẹẹ fun eleyii ni pe. O ni:

Araba ni baba, ara ba ni baba ẹni ti a ba la ba ni baba. Ẹni ti a ba ninu ahere ni baba a difa fun Baba Imọle abiewu gẹrẹjẹ eyi ti o fi gbogbo aiye ṣe ọfẹ jẹ. Ta ni baba eriwo. Araba ni baba eriwo. Araba…

Ifa ni keleyii o gba agba to ba ti jẹ aṣaju rẹ, ko ma gba pe baba ni. Ifa ni nigba naa ni o laseyọri. Ifa sọ fun eleyun baun. Bẹẹ ni ta ba… n tifa ba sọ fun. Ko huwa daadaa, ko ma ṣe daadaa. Ifa la… o laseyọri, o lo wa fun un.

Otura Meji 3:
Ifa leleyii si wẹ, yio lọ mọ iwọn ara rẹ. Ẹni ta ba da da Ifa yii fun. Ko lọ mọwọn ara rẹ. Kọ ma ṣe ṣe arimi. Nitori pe n tifa fi n ki lọ fun eleyii pe keleyii o lọ mu ara, ko ma ṣe ṣe arimi pe aarin ọta lo wa. Aarin ọta lo wa o. To ba si ni suuru daadaa, to kun fadura, Ifa ni yio ṣẹgun awọn ọta un, ti o wa di ọba le gbogbo wọn lori patapata. Ti o dọba le wọn lori. Loju Otura Meji. Bẹẹ ni ibi tifa gba to fi sọ bẹẹ nii…. Fun eleyii. O ni:

Ọna kan ti n ihin wa, ọna kan ti ohun wa. Ipade ọna meji a bi ẹnu ṣonṣo a dia fun Erinmọdo eyi ti o mu jọba igi loko. Ifa lo wa ferinmọdo jọba.

Erinmọdo re, hmm, oun na mu jọba igi loko. Wọn ni kerinmọdo o rubọ nigba igba iwasẹ. Nitori pe, aarin ọta lo wa. Gbogbo ẹgbẹ rẹ patapata, wọn bori ẹ ni. Wọn ba ṣọta pe, ṣoun ni kan ni. Ṣoun ni kan lo rẹwa ni. Wọn ṣa n ditẹ mọ ọ. O wa meji kẹta, [o daarun] o gboko awo lọ. Oun na kuro ninu iyanjẹ ibi. O loun yio ṣẹgun ọta. O meji, kẹta, o daarun, o gboko awo lọ. O fowo Ifalẹ, a dafa fun un. Awọn babalawo sọ fun un pe oun le ṣẹgun ọta, ninu ohun to bọ si naa ni. Naa lo da…Ni eleyii dafa si. O ni bẹẹ ni, ni ko rubọ. Wọn ni to ba ti rubọ, wọn ni gbogbo ohun tan a fi iya jẹun, tan ba ṣọta oun, ni o wa dọba le [wọn] lori i. Bọ Ọrunmila ṣe ṣefa fun Erinmọdo nu un. Bo ṣe dọba le gbogbo wọn lori nu un. Tẹ ba kirinmọdo ni ninu igbo doni doni, o rẹwa, rabata bayii lori, kosi ohunn ti wọn o fi ṣe. Bẹẹni, ni n ba n jo ni n ba n yọ. Ngbo o ṣẹgun ọta tan. O ni bẹẹ babalawo toun [wi] bẹẹ, babalawo toun sọ:

Ọna kan ti n ihin wa, ọna kan ti ohun wa. Ipade ọna meji a bi ẹnu ṣonṣo a dia fun Erinmọdo eyi ti o kẹhin igi loko. Ifa lo wa ferinmọdo jọba. Ọrunmila lo gberimọdo niyawo. Ifa waa ferinmọdo jọba.

On ṣe Ifa wa ferinmọdo jọba ooo.
Ifa wa ferinmọdọ jọba.
Ọrunmila lo gberinmọdo niyawo.
Ifa wa ferinmọdo jọba.

Bo ṣe jẹ ọba le gbogbo awọn igi ẹgbẹ rẹ lori nu. Ifa ni eleyii yio dọba le gbogbo awọn ota lori, ko… ko rubọ nbẹ. Bẹẹ ni, Ifa lo sọ bẹẹ. Loju Otura Meji naa ni.

Otura Meji 4:
Ifa tun sọ fun eleyii naa, huh, ko mọ iwọn ara rẹ, aarin ọta lo wa. Tori ojọjumọ nan… fi ṣepe, gbogbo ohun ti n ṣe o tẹ wọn lọrun. Ṣugbọn gbogbo epe ti wọn ṣe yii, to ba ti le rubọ, tawọn babalawo jawe Ifa fun un, Ifa lepe naa yio yi pada ti o mu ni lari ni. Ti o lowo lọwọ, ti o la, ju gbogbo ti wọn ba ṣe ọta lọ. Ifa lo sọ bẹẹ. Nibi Ifa gba to fi sọ bẹẹ ni o. O ni:

Ka mu irin pọnna ka fi ya ọmọ loju, ka fi esi ya ọmọ lọrun, baba wọn ku o, won o jogun ẹru. Iya wọn ku o, wọn o jogun ilẹkẹ. Bẹẹni won o jogun akisa jinni a difa fun Ọrunmila. Wọn fi jojumọ wọn fi baba ṣepe,

Wọn ni ki baba Ọrunmila o rubọ, nigba awọn babalawo da a, wọn ni [ko] rubọ. Gbogbo wọn tan ṣepe fun baba yii. Pe ayipada rẹ owo ni baba o fi ni o. Bi baba ṣe ṣetutu nu o. Baba gbọ riru o ru o, baba gbọ titu o tu. O gbọ oharaka ẹbọ loju ọpọn, o ha. Aṣẹhin wa, aṣẹhin bọ, Ifa wa ba baba ni jẹbutu ire. Baba n jo, baba n yọ. O ni bẹẹ nan babalawo toun wi, o ni:

Ka mu irin pọnna ka fi ya ọmọ loju, ka fi esi ya ọmọ lẹka lọrun, baba wọn ku o, won o jogun ẹru. Iya wọn ku o, wọn o jogun ilẹkẹ, bẹẹni won o jogun akisa jinni a difa fun Ọrunmila. Wọn fi jojumọ wọn fi baba ṣepe, n jẹ bi ẹ ba gbe mi ṣepe ngba yii bi n ṣai ni owo lọwọ. Egbo ẹgbo, ẹwa ẹwa, bẹ ṣe n gbe mi ṣepe nigba yii mo fi faya laya. Ẹgbo ẹgbo, ẹwa ẹwa, bẹ ṣe n gbe mi ṣepe nigba yii mo fi n bimọ lemọ. Egbo egbo, ẹwa ẹwa, bẹ tun ṣe n gbe mi ṣepe nigba yii mo wa nire gbogbo. Egbo egbo...

Ifa ni keleyii o lọ rubọ, Ifa nire gbogbo ni o… ni o ni nbẹ. Gbogbo ọta tan ba ṣe ayipada yio de ti o dolowo. Bẹẹ ni Ifa sọ loju… loju Otua Meji. Abọru aboye, nifa. Ifa sọ bẹẹ.

Otura Meji 1:
The Ifa sign that is cast here, Otura Meji is the sign here. Anyone for whom it is cast, Ifa says this person should focus on his/her religion. If (s)he is a Muslim, (s)he should go to Qur’anic school. (S)he should focus intensely on his/her religion, go to Qur’anic school, if (s)he is a Muslim. If he is a babalawo, and comes from a line of Muslims, he should study and practice the two religions together. Ifa says success is there for this person. (S)He should be diligent in Islamic studies because this is his/her path in life. This is what Otura Meji says. Ifa says if (s)he studies Islam, everything will be easy for him/her. Success will come to this person. Ifa says so in Otura Meji. This is how Ifa said it, Ifa said:

Dagadamba n fura ọsẹyẹ oko gbọ mọle Aworokonjobi a dia fun Ọrunmila. Baba n lọ re gba gambi, a gba gambi o, a gba a wa, a le we lawani a gbe ede bọrun. Ifa wa wa di mọle.

[Dagadamba n fura it makes a bird in the bush to understand Islam, Aworokonjobi cast Ifa for Ọrunmila. Baba went to collect Gambi. We received Gambi o, we brought it back. We can don the turban, and we can speak their langauge. Our Ifa became Muslim.]

Ifa says this person should go to Qur’anic school. If (s)he does so, (s)he will find success there. The way will be made easy for him/her. This is what Ifa says in Otura Meji.

Otura Meji 2:
Ifa also says for this person that (s)he should be very careful. (S)He should recognize that there are powerful people out there. (S)He should accept the person who (s)he meets as his/her boss or master so that (s)he may find success. This is because (s)he will be treated in the same way (s)he acts. Ifa says when (s)he accepts that person, that (s)he should not behave poorly toward his/her leader. (S)He should not be disrespectful, and that (s)he will receive the same treatment that (s)he gives his/her leader. Ifa says that if (s)he has respect for his/her elder and accepts the person who is above him/her, the boss/master, Ifa says (s)he will succeed. Otura Meji says so. This is how Ifa said it for this person. Ifa said:

Araba ni baba, ara ba ni baba ẹni ti a ba la ba ni baba. Ẹni ti a ba ninu ahere ni baba a difa fun Baba Imọle abiewu gẹrẹjẹ eyi ti o fi gbogbo aiye ṣe ọfẹ jẹ. Ta ni baba eriwo. Araba ni baba eriwo. Araba…

[The high priest of Ifa is the leader, the person related to you is your father. The person who precedes you is your leader; the person you meet in the hut is your leader cast Ifa for Baba Imọle (the Prophet Muhammed) with a long flowing gown the one who claimed the whole world as his own. Who is the leader of the scholars? The Araba is their leader.]

Ifa says that this person should accept his/her seniors or superiors and respect their authority. Ifa says that is how (s)he will succeed. Ifa says so for that person. Yes, this is what Ifa said, that (s)he should behave well, and do well by his/her master. Ifa says success is there for him/her.

Otura Meji 3:
Ifa also says for this person that this particular one must know his/her limits. (S)He shouldn’t show off or try to be something (s)he is not, because Ifa warns this person to be careful and not to show off since (s)he is in the midst of enemies. If (s)he is very patient, and is diligent in prayer, Ifa says (s)he will defeat his/her enemies, and (s)he will become the ruler over every last one of them. (S)He will rule over them in Otura Meji. Yes, this is how Ifa said it for this person. Ifa said:

Ọna kan ti n ihin wa, ọna kan ti ohun wa. Ipade ọna meji a bi ẹnu ṣonṣo a dia fun Erinmọdo eyi ti o mu jọba igi loko. Ifa lo wa ferinmọdo jọba.

[A raod leads from here, a road leads from there. When two roads merge, they taper down, cast Ifa for the Erinmọdo tree who who was made king over the trees in the forest. Ifa declared Erinmọdo king.]

Ẹrinmọdo, hmm, he is the one they made king of the trees in the forest. Erinmọdo was instructed to offer a sacrifice in the time of the ancestors because she was surrounded by enemies. Every last one of her mates was more successful than she was. They antagonized her, saying, “Is she the only one? Is she the only one who is beautiful?” So they plotted against her. Erinmọdo put two and two together and realized that she needed the advice of Ifa. She said she must find a way out of this trouble and defeat her enemies. She decided that she must seek the help of Ifa priests and went to consult Ifa. The babalawo told her that she would defeat her enemies in the matter at hand. They said she should offer a sacrifice, so that all the suffering that her enemies were trying to inflict on her, everyone who had become her enemy, she would rule over them. That is what Ọrunmila did for Erinmọdo and she came to rule over all of the other trees. Up until today, if you see Erinmọdo, it is beautiful and enourmous like this, and there is nothing anyone can do about it. She danced and rejoiced when she defeated her enemies. She said, my babalawo told me so, my babalawo said:

Ọna kan ti n ihin wa, ọna kan ti ohun wa. Ipade ọna meji a bi ẹnu ṣonṣo a dia fun Erinmọdo eyi ti o kẹhin igi loko. Ifa lo wa ferinmọdo jọba. Ọrunmila lo gberimọdo niyawo. Ifa waa ferinmọdo jọba.

[A raod leads from here, a road leads from there. When two roads merge, they taper down, cast Ifa for the Erinmọdo tree who who was made king over the trees in the forest. Ifa declared Erinmọdo king.]

On ṣe Ifa wa ferinmọdo jọba ooo.
Ifa wa ferinmọdọ jọba.
Ọrunmila lo gberinmọdo niyawo.
Ifa wa ferinmọdo jọba.

[She sang: Ifa made Erinmọdo the king ooo.
Ifa made Erinmọdo the king.
Ọrunmila took Erinmọdo as his wife.
Ifa made Erinmọdo the king.]

Otura Meji 4:
Ifa also says for this person, huh, that (s)he should know his/her place, because (s)he is in the midst of enemies. Everyday people are trying to curse him/her, and everything that (s)he is doing does not please them. However, all of the curses they try to place on him/her, if (s)he offers a sacrifice and the babalawo prepare medicine for him/her, Ifa says the curses will be turned into blessings. (S)he will become rich, richer than all of his/her enemies. Ifa says so. This is how Ifa said it, Ifa said:

Ka mu irin pọnna ka fiya ọmọ loju, ka fi esi ya ọmọ lọrun baba wọn ku o, won o jogun ẹru. Iya wọn ku o, wọn o jogun ilẹkẹ, bẹẹni won o jogun akisa jinni a difa fun Ọrunmila. Wọn fi jojumọ wọn fi baba ṣepe,

[Let us take iron to make the tribal marks, let us mark the face of the child, let use a hot leave (like stinging nettle) to mark the neck of the child, their father died, they did not inherit any slaves. When the mother died, they did not inherit her beads. They did not even inherit the clothes of their father is the one who cast Ifa for Ọrunmila when they were cursing him everyday.]

The babalawo told Ọrunmila to offer a sacrifice when they cast this Ifa sign. All of his enemies were trying to curse him. Baba turned the curse into money. Baba quickly made a sacrifice. He did everything asked of him and followed directions exactly. Not long after that, Ifa met him in the midst of blessings. Baba was dancing and rejoicing. He said his babalawo had told him it would be so. He said:

Ka mu irin pọnna ka fi ya ọmọ loju, ka fi esi ya ọmọ lọrun, baba wọn ku o, won o jogun ẹru. Iya wọn ku o, wọn o jogun ilẹkẹ, bẹẹni won o jogun akisa jinni a difa fun Ọrunmila. Wọn fi jojumọ wọn fi baba ṣepe, n jẹ bi ẹ ba gbe mi ṣepe ngba yii bi n ṣai ni owo lọwọ. Egbo ẹgbo, ẹwa ẹwa, bẹ ṣe n gbe mi ṣepe nigba yii mo fi faya laya. Ẹgbo ẹgbo, ẹwa ẹwa, bẹ ṣe n gbe mi ṣepe nigba yii mo fi n bimọ lemọ. Egbo egbo, ẹwa ẹwa, bẹ tun ṣe n gbe mi ṣepe nigba yii mo wa nire gbogbo. Egbo egbo...

[Let us take iron to make the tribal marks, let us mark the face of the child, let use a hot leave (like stinging nettle) to mark the neck of the child, their father died, they did not inherit any slaves. When the mother died, they did not inherit her beads. They did not even inherit the clothes of their father is the one who cast Ifa for Ọrunmila when they were cursing him everyday. I may not have money when you try to curse me. When you try to curse me, I will use it to have many wives. When you try to curse me, I will use it to have many children. When you try to curse me, I will use it to get all kinds of blessings…]

Ifa says that this person should offer a sacrifice and (s)he will receive all kinds of blessings. Everything his/her enemies are doing will turn into a blessing of money. Ifa says so in Otua Meji.

African Language Program at Harvard University